Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions

636 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

  2. Àwọn baba wa jẹ manna ní aginjù; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá fún wọn jẹ.’ ”

  3. A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá.

  4. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”

  5. Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’?

  6. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

  7. “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni; wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

  8. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

  9. “Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

  10. Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

  11. “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ, èmi mọ àwọn tí mo yàn, ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’

  12. Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

  13. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.” Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.

  14. Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.”

  15. Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

  16. Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé, “ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’ àti, “ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

  17. “Ọlọ́run wí pé, ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran, àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá,

  18. àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi obìnrin, ni Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mi jáde ni ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀.

  19. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run, àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀; ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;

  20. A ó sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.

  21. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

  22. Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò.

  23. Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

  24. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

  25. Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’