Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: Acts 8:32, »He was led as a sheep to the slaughter...«

4 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Acts 8:32, »He was led as a sheep to the slaughter...«

  1. A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

  2. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

  3. Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.

  4. Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún. Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀? Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”