Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: Hebrews 2:6, »What is man, that thou art mindful of him...«
Àwọn ẹsẹ nípa Hebrews 2:6, »What is man, that thou art mindful of him...«
kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀, àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ, ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ; ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ; ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.