Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions

636 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a, akọ àti abo ni ó dá wọn.

  2. Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe.

  3. Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

  4. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

  5. Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.

  6. Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”

  7. Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

  8. Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

  9. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún.

  10. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.

  11. A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.

  12. Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà.

  13. Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀.

  14. ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”

  15. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.

  16. nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,

  17. àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”

  18. Olúwa sì wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ; àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

  19. Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin.

  20. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?”

  21. Ọkùnrin náà sì dáhùn pé, “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.”

  22. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”

  23. Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.

  24. Olúwa si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.

  25. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi.