Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: 1 Peter 1:24, »For all flesh is as grass...«
Àwọn ẹsẹ nípa 1 Peter 1:24, »For all flesh is as grass...«
Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.” Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
Nítorí pé, “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko. Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.” Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.