Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: John 15:25, »They hated me without a cause.«
Àwọn ẹsẹ nípa John 15:25, »They hated me without a cause.«
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ lórí ì mi; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi lọ, púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run. A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí
Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’