Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: 1 Peter 3:10, »For he that will love life...«
Àwọn ẹsẹ nípa 1 Peter 3:10, »For he that will love life...«
Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”