Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: Hebrews 10:16, »This is the covenant that I will make...«

7 ẹsẹ · 252 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Hebrews 10:16, »This is the covenant that I will make...«

  1. “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.

  2. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni Olúwa wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

  3. Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

  4. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’ nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà.

  5. Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”

  6. “Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn, inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

  7. Ó tún sọ wí pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”