Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: Hebrews 3:7, »To day if ye will hear his voice...«
Àwọn ẹsẹ nípa Hebrews 3:7, »To day if ye will hear his voice...«
nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀. Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò tí wọn wádìí mi, tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.
Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má ṣe sé ọkàn yín le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀, bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù,
níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn; wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”