Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quotations and Allusions: Romans 3:10, »There is none righteous, no, not one...«
Àwọn ẹsẹ nípa Romans 3:10, »There is none righteous, no, not one...«
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.
Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,
kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”