Skip to content

Sodom

47 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Sodoma

31.1900, 35.3900 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Sodom

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.

  2. Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.)

  3. Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu.

  4. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.

  5. jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari) jagun.

  6. Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu,

  7. Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.

  8. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.

  9. Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀.

  10. Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (èyí ni àfonífojì Ọba).

  11. Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”

  12. Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,

  13. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Sodomu, Abrahamu sì sìn wọ́n dé ọ̀nà.

  14. Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ.

  15. Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

  16. Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”

  17. Ní àṣálẹ́, àwọn angẹli méjì sì wá sí ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dìde láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sì foríbalẹ̀ fún wọn.

  18. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Sodomu tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká.

  19. Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.

  20. Ó sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

  21. Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Seboimu, tí Olúwa bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀.

  22. Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra. Èso àjàrà wọn kún fún oró, ìdì wọn korò.

  23. Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sodomu, a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

  24. Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!

  25. Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.