Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 1:1nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

  2. Matiu 1:2nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

  3. Matiu 1:3nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu;

  4. Matiu 1:4nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni;

  5. Matiu 1:5nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  6. Matiu 1:6nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

  7. Matiu 1:7nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa,

  8. Matiu 1:8nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Asa ni baba Jehoṣafati; Jehoṣafati ni baba Jehoramu; Jehoramu ni baba Ussiah;

  9. Matiu 1:9nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah;

  10. Matiu 1:10nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah;

  11. Matiu 1:11nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

  12. Matiu 1:12nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli: Jekoniah ni baba Ṣealitieli; Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

  13. Matiu 1:13nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Serubbabeli ni baba Abihudi; Abihudi ni baba Eliakimu; Eliakimu ni baba Asori;

  14. Matiu 1:14nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Asori ni baba Sadoku; Sadoku ni baba Akimu; Akimu ni baba Elihudi;

  15. Matiu 1:15nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Elihudi ni baba Eleasari; Eleasari ni baba Mattani; Mattani ni baba Jakọbu;

  16. Matiu 1:16nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

  17. Matiu 1:17nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

  18. Matiu 1:18nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyí, ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

  19. Matiu 1:19nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

  20. Matiu 1:20nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.

  21. Matiu 1:21nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

  22. Matiu 1:22nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé:

  23. Matiu 1:23nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).

  24. Matiu 1:24nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya.

  25. Matiu 1:25nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.