Skip to content

John

89 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan John

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea.

  2. Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

  3. Nígbà náà ni Jesu ti Galili wá sí odò Jordani kí Johanu bá à lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

  4. Ṣùgbọ́n Johanu kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ìbá bamitiisi fún mi, ìwọ sì tọ̀ mí wá?”

  5. Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili.

  6. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

  7. Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

  8. Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí.

  9. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi?

  10. Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ.

  11. Láti ìgbà ọjọ́ Johanu onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di à fi agbára wọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.

  12. Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó sọtẹ́lẹ̀ kí Johanu kí ó tó dé.

  13. Nítorí Johanu wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’

  14. ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

  15. Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀,

  16. nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”

  17. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”.

  18. Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.

  19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

  20. Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni.

  21. Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

  22. Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”

  23. Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

  24. Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

  25. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.