Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Miracles

338 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀.

  2. Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

  3. Mose dáhùn ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”

  4. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”

  5. Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un.

  6. Nígbà náà ni Olúwa wá sọ fún un pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀.

  7. Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”

  8. Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  9. Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù.

  10. Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́.

  11. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”

  12. Ní ìgbà náà ni Mose sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti rán fún Aaroni àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Farao.

  13. Mose àti Aaroni pe gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ.

  14. Aaroni sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe iṣẹ́ àmì náà ní ojú àwọn ènìyàn náà.

  15. Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Israẹli wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.

  16. Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.”

  17. Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀.

  18. Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rú ẹbọ sí Olúwa.”

  19. Mose sọ fún Farao pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Naili nìkan.”

  20. Farao wí pé, “Ni ọ̀la.” Mose sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa.

  21. àwọn onídán sì sọ fún Farao pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Farao sì yigbì, kò sì fetísílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

  22. “ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí.

  23. nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.

  24. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

  25. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.