- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 1:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé,
- Numeri 1:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
- Numeri 1:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.
- Numeri 1:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.
- Numeri 1:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: “Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
- Numeri 1:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
- Numeri 1:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.
- Numeri 1:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Suari.
- Numeri 1:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni.
- Numeri 1:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu: láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu. Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri.
- Numeri 1:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni.
- Numeri 1:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
- Numeri 1:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri.
- Numeri 1:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli.
- Numeri 1:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”
- Numeri 1:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.
- Numeri 1:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí
- Numeri 1:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,
- Numeri 1:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.
- Numeri 1:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
- Numeri 1:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).
- Numeri 1:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ìran Simeoni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
- Numeri 1:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).
- Numeri 1:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Láti ìran Gadi, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn.
- Numeri 1:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650).