- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1406–1380 BC
Conquest of Canaan
Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joṣua 1:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose,
- Joṣua 1:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli.
- Joṣua 1:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose.
- Joṣua 1:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.
- Joṣua 1:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.
- Joṣua 1:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.
- Joṣua 1:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.
- Joṣua 1:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.
- Joṣua 1:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
- Joṣua 1:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀,
- Joṣua 1:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ”
- Joṣua 1:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé,
- Joṣua 1:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
“Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa pa fún yín: ‘Olúwa Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’
- Joṣua 1:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Mose fún un yin ní ìlà-oòrùn Jordani; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́
- Joṣua 1:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
títí Olúwa yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún un yin ní agbègbè ìlà-oòrùn ti Jordani.”
- Joṣua 1:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pàṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe, ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ.
- Joṣua 1:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́rọ̀ sí Mose nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Mose.
- Joṣua 1:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò pàṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ sá à ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”
- Joṣua 2:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Joṣua ọmọ Nuni rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àṣírí láti Ṣittimu. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jeriko.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé panṣágà kan, tí à ń pè ní Rahabu wọ́n sì dúró síbẹ̀.
- Joṣua 2:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
A sì sọ fún ọba Jeriko, “Wò ó! Àwọn ará Israẹli kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò.”
- Joṣua 2:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ọba Jeriko sì ránṣẹ́ sí Rahabu pé, “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni.”
- Joṣua 2:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “Lóòtítọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá.
- Joṣua 2:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò láti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.”
- Joṣua 2:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.)
- Joṣua 2:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.