Skip to content

Gibeon

35 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Gibeonite

31.8400, 35.1800 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gibeon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí Jeriko àti Ai,

  2. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu.

  3. Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.

  4. Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun.

  5. “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”

  6. Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.

  7. Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé, “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”

  8. Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.

  9. Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Aijaloni.”

  10. Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni.

  11. Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Israẹli ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hifi tí wọ́n ń gbé ní Gibeoni, gbogbo wọn ló bá a jagun.

  12. Gibeoni, Rama, Beeroti,

  13. Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní: Gibeoni, Geba,

  14. Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni.

  15. Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.

  16. Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gibeoni ti à ń pè ni Helikatihu Hasurimu.

  17. Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni.

  18. (Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.)

  19. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.

  20. Ọba sì lọ sí Gibeoni láti rú ẹbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Solomoni sì rú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

  21. Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”

  22. Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni.

  23. Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,

  24. Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka,

  25. Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera,