Skip to content

Hebron

56 verses

31.5300, 35.0900 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Hebron

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

  2. Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.

  3. Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani.

  4. Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre nítòsí i Kiriati-Arba (ti o túmọ̀ sí Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé.

  5. Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.)

  6. Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,

  7. Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.

  8. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni.

  9. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú.

  10. Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.

  11. Ní àkókò náà ni Joṣua lọ tí ó sì run àwọn ará Anaki kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hebroni, Debiri, àti ní Anabu, àti gbogbo ilẹ̀ Juda, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Israẹli. Joṣua sì run gbogbo wọn pátápátá àti ìlú wọn.

  12. ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan ọba Hebroni, ọ̀kan

  13. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni Hebroni jẹ́ ti Kalebu ọmọ Jefunne ará Kenissiti láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tọkàntọkàn.

  15. (Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.) Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.

  16. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.)

  17. Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀

  18. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda.

  19. Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.)

  20. Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina,

  21. Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai.

  22. Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta.

  23. Ṣùgbọ́n Samsoni sùn níbẹ̀ di àárín ọ̀gànjọ́. Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábùú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hebroni.

  24. Àti àwọn tí ó wà ni Hebroni, àti sí gbogbo àwọn ìlú ti Dafidi tìkára rẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìn ká.

  25. Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.”