- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 2100–1900 BC
Abraham: The Covenant
God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.
“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì bùkún fún ọ; èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.
Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”
Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani.
Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀.
Abramu sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni More ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani sì wà ní ilẹ̀ náà.
Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.
Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.
Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù.
- Gẹnẹsisi 12:10nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Abramu sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.
- Gẹnẹsisi 12:11nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Ejibiti, ó wí fún Sarai, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ,
- Gẹnẹsisi 12:12nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
nígbà tí àwọn ará Ejibiti bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.
- Gẹnẹsisi 12:13nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”
- Gẹnẹsisi 12:14nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Abramu dé Ejibiti, àwọn ará Ejibiti ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.
- Gẹnẹsisi 12:15nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Nígbà tí àwọn ìjòyè Farao sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú Farao, wọ́n sì mú un lọ sí ààfin.
- Gẹnẹsisi 12:16nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Ó sì kẹ́ Abramu dáradára nítorí Sarai, Abramu sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú ìbákasẹ.
- Gẹnẹsisi 12:17nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn búburú sí Farao àti ilé rẹ̀, nítorí Sarai aya Abramu.
- Gẹnẹsisi 12:18nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Abramu, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe?
- Gẹnẹsisi 12:19nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí o sì máa lọ.”
- Gẹnẹsisi 12:20nǹkan bí 1920 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.
- Gẹnẹsisi 13:1nǹkan bí 1918 ṣáájú Kristi
Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú.
- Gẹnẹsisi 13:2nǹkan bí 1918 ṣáájú Kristi
Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.
- Gẹnẹsisi 13:3nǹkan bí 1918 ṣáájú Kristi
Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai.
- Gẹnẹsisi 13:4nǹkan bí 1918 ṣáájú Kristi
Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.
- Gẹnẹsisi 13:5nǹkan bí 1918 ṣáájú Kristi
Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́.