Skip to content

Canaan

76 verses · 4 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Canaanitish, Chanaan, city

31.6900, 34.8400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Canaan

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

  2. Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀.

  3. Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu.

  4. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.

  5. Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé. Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

  6. Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.

  7. Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani.

  8. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kójọ ni Padani-Aramu, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kenaani.

  9. Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé, àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà.

  10. Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (ti o túmọ̀ sí Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.

  11. Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.

  12. Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.

  13. Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

  14. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.

  15. Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.”

  16. Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

  17. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé,

  18. Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’

  19. A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kenaani. Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ?

  20. Farao wí fún Josẹfu pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kenaani,

  21. Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

  22. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

  23. Àwọn ọmọkùnrin Simeoni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani.

  24. Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.

  25. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá.