Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Holy Land

108 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni.

  2. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀.

  3. Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí.

  4. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín, ilẹ̀ náà gbọdọ̀ sinmi fún Olúwa.

  5. Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ.

  6. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ.

  7. Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkára rẹ̀ hù, ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan.

  8. Olúwa sọ fún Mose pé,

  9. “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

  10. Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.

  11. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakkuri;

  12. láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;

  13. láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;

  14. láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;

  15. láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;

  16. láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;

  17. láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;

  18. láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;

  19. láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;

  20. láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

  21. láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;

  22. láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.

  23. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)

  24. Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè.

  25. Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.