Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Holy Land: Divided by lot

22 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Divided by lot

  1. Olúwa sọ fún Mose pé,

  2. “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni.

  3. Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

  4. “Èyí ni orúkọ wọn: “Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;

  5. Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;

  6. Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;

  7. Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;

  8. Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,

  9. Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;

  10. Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;

  11. Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;

  12. Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;

  13. Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”

  14. Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

  15. pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.”

  16. Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.

  17. Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni.

  18. Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni.

  19. Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka,

  20. ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.

  21. Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.

  22. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.