Fò sí àkóónú

Canaan

76 verses · 4 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Canaanitish, Chanaan, city

31.6900, 34.8400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Canaan

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani,

  2. Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jordani, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kenaani tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí.

  3. “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn.

  4. Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.

  5. Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kenaani, tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Israẹli pín fún wọn.

  6. Ní Ṣilo, ní Kenaani, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mose pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”

  7. Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.

  8. Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani.

  9. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli,

  10. Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kenaani láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ní Gileadi, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ.

  11. Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki,

  12. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani.

  13. Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu.

  14. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

  15. Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

  16. “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà; àwọn ọba Kenaani jà ní Taanaki ní etí odo Megido, ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.

  17. Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani.

  18. “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.”

  19. “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

  20. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

  21. Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:

  22. Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

  23. Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

  24. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti; ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani, ilẹ̀ àwọn ara Filistini. “Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”

  25. “Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ.