Fò sí àkóónú

circa 2100–1900 BC

Abraham: The Covenant

God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.

394 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 25:16nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.

  2. Gẹnẹsisi 25:17nǹkan bí 1773 ṣáájú Kristi

    Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.

  3. Gẹnẹsisi 25:18nǹkan bí 1773 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo.

  4. Gẹnẹsisi 25:19nǹkan bí 1896 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki.

  5. Gẹnẹsisi 25:20nǹkan bí 1856 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó.

  6. Gẹnẹsisi 25:21nǹkan bí 1837 ṣáájú Kristi

    Isaaki sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rebeka sì lóyún.

  7. Gẹnẹsisi 25:22nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa.

  8. Gẹnẹsisi 25:23nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ; àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

  9. Gẹnẹsisi 25:24nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó tó àkókò fún un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n.

  10. Gẹnẹsisi 25:25nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau.

  11. Gẹnẹsisi 25:26nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn.

  12. Gẹnẹsisi 25:27nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú.

  13. Gẹnẹsisi 25:28nǹkan bí 1836 ṣáájú Kristi

    Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu.

  14. Gẹnẹsisi 25:29nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kan, Jakọbu sì pa ìpẹ̀tẹ̀, Esau sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.

  15. Gẹnẹsisi 25:30nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.)

  16. Gẹnẹsisi 25:31nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Jakọbu dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.”

  17. Gẹnẹsisi 25:32nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Esau sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?”

  18. Gẹnẹsisi 25:33nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n, Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Esau búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jakọbu.

  19. Gẹnẹsisi 25:34nǹkan bí 1805 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Jakọbu fi àkàrà àti ìpẹ̀tẹ̀ lẹntili fún Esau. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Báyìí ni Esau gan ogún ìbí rẹ̀.