- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 2100–1900 BC
Abraham: The Covenant
God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 24:58nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì pe Rebeka wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ.”
- Gẹnẹsisi 24:59nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì gbà kí Rebeka àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Abrahamu àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ máa lọ.
- Gẹnẹsisi 24:60nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé, “Ìwọ ni arábìnrin wa ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.”
- Gẹnẹsisi 24:61nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
- Gẹnẹsisi 24:62nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé.
- Gẹnẹsisi 24:63nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá.
- Gẹnẹsisi 24:64nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ,
- Gẹnẹsisi 24:65nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 24:66nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Isaaki ohun gbogbo tí ó ti ṣe.
- Gẹnẹsisi 24:67nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Isaaki mú Rebeka wọ inú àgọ́ ìyá rẹ̀, Sara, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Isaaki lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 25:1nǹkan bí 1853 ṣáájú Kristi
Abrahamu sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura.
- Gẹnẹsisi 25:2nǹkan bí 1852 ṣáájú Kristi
Ó sì bí Simrani, Jokṣani, Medani, Midiani, Iṣbaki, àti Ṣua
- Gẹnẹsisi 25:3nǹkan bí 1824 ṣáájú Kristi
Jokṣani ni baba Ṣeba àti Dedani, àwọn ìran Dedani ni àwọn ara Asṣuri, Letusi àti Leumiti.
- Gẹnẹsisi 25:4nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Midiani ni Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.
- Gẹnẹsisi 25:5nǹkan bí 1829 ṣáájú Kristi
Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki.
- Gẹnẹsisi 25:6nǹkan bí 1829 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn.
- Gẹnẹsisi 25:7nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).
- Gẹnẹsisi 25:8nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Abrahamu sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin ín sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 25:9nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti,
- Gẹnẹsisi 25:10nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí.
- Gẹnẹsisi 25:11nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọ́run sì bùkún fún Isaaki ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòsí kànga Lahai-Roi ní ìgbà náà.
- Gẹnẹsisi 25:12nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un.
- Gẹnẹsisi 25:13nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí: Nebaioti àkọ́bí, Kedari, Adbeeli, Mibsamu,
- Gẹnẹsisi 25:14nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Miṣima, Duma, Massa,
- Gẹnẹsisi 25:15nǹkan bí 1821 ṣáájú Kristi
Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema.