Skip to content

Ai

31 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Hai

31.9100, 35.2600 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ai

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

  2. Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai.

  3. Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò.

  4. Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.”

  5. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá.

  6. Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìndínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami.

  7. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

  8. Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

  9. Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.

  10. Nígbà náà ni Joṣua rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárín Beteli àti Ai, ní ìwọ̀-oòrùn Ai. Ṣùgbọ́n Joṣua wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní òru ọjọ́ náà.

  11. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Joṣua kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Israẹli, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Ai.

  12. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.

  13. Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà.

  14. Nígbà tí ọba Ai rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà.

  15. A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ai jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Joṣua títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà.

  16. Kò sì ku ọkùnrin kan ní Ai tàbí Beteli tí kò tẹ̀lé Israẹli. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè ìlú náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli.

  17. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai.

  18. Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.

  19. Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai.

  20. Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Ai láààyè, wọ́n sì mu un tọ Joṣua wá.

  21. Nígbà tí Israẹli parí pípa gbogbo àwọn ìlú Ai ní pápá àti ní aginjù ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, tí gbogbo wọ́n sì ti ojú idà ṣubú, tí a fi pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Israẹli sì padà sí Ai, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú.

  22. Ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà—gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Ai.

  23. Nítorí tí Joṣua kò fa ọwọ́ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Ai run.

  24. Joṣua sì jó Ai, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí.

  25. Ó sì gbé ọba Ai kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí oòrùn sì ti wọ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.