Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Family

44 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

  2. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

  3. Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.

  4. Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

  5. Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai.

  6. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

  7. Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ.

  8. Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.

  9. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.”

  10. Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

  11. Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

  12. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.

  13. Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.

  14. Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà yín, láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ.

  15. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.

  16. Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.

  17. Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa.

  18. Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.

  19. Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali.

  20. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.

  21. Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”

  22. Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí.

  23. Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru.

  24. Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

  25. “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?”