Skip to content

Silas

17 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Silvanus

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Silas

  1. Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.

  2. Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.

  3. Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.

  4. Notwithstanding it pleased Silas to abide there still.

  5. Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.

  6. Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Paulu àti Sila, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ.

  7. Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run, àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.

  8. Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila.

  9. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.

  10. Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ.

  11. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun, ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea.

  12. Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

  13. Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.

  14. Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.

  15. Paulu, Sila àti Timotiu, A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi: Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.

  16. Paulu, Sila àti Timotiu, Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

  17. Nítorí Sila, arákùnrin wa olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkúrú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.