Skip to content

Macedonia

21 verses

40.6300, 22.9300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Macedonia

  1. Ìran kan si hàn sì Paulu ni òru, ọkùnrin kan ará Makedonia dúró, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”

  2. Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedonia, a ka á sí pé, Ọlọ́run tí pè wá láti wàásù ìyìnrere fún wọn.

  3. láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòó kan.

  4. Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.

  5. Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.”

  6. Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.

  7. Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia.

  8. Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ.

  9. Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  10. Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia.

  11. Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea.

  12. síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.

  13. Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú.

  14. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia.

  15. Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.

  16. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.

  17. Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo.

  18. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia.

  19. Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀.

  20. Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀.

  21. Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́