Skip to content

Creation Era

Creation & The Fall

God creates the heavens and earth, forming humanity in his image before sin enters the world.

138 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 1:1nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.

  2. Gẹnẹsisi 1:2nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

  3. Gẹnẹsisi 1:3nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.

  4. Gẹnẹsisi 1:4nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.

  5. Gẹnẹsisi 1:5nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

  6. Gẹnẹsisi 1:6nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.”

  7. Gẹnẹsisi 1:7nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  8. Gẹnẹsisi 1:8nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “ọ̀run.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.

  9. Gẹnẹsisi 1:9nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  10. Gẹnẹsisi 1:10nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.

  11. Gẹnẹsisi 1:11nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  12. Gẹnẹsisi 1:12nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára.

  13. Gẹnẹsisi 1:13nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹta.

  14. Gẹnẹsisi 1:14nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.

  15. Gẹnẹsisi 1:15nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  16. Gẹnẹsisi 1:16nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú.

  17. Gẹnẹsisi 1:17nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀,

  18. Gẹnẹsisi 1:18nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

  19. Gẹnẹsisi 1:19nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

  20. Gẹnẹsisi 1:20nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.”

  21. Gẹnẹsisi 1:21nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

  22. Gẹnẹsisi 1:22nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.”

  23. Gẹnẹsisi 1:23nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ karùn-ún.

  24. Gẹnẹsisi 1:24nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  25. Gẹnẹsisi 1:25nǹkan bí 4004 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.