Skip to content

Creation Era

The Great Flood

Humanity's wickedness fills the earth; God preserves Noah and his family through a catastrophic flood.

97 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 6:1nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin.

  2. Gẹnẹsisi 6:2nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.

  3. Gẹnẹsisi 6:3nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

  4. Gẹnẹsisi 6:4nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

  5. Gẹnẹsisi 6:5nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo.

  6. Gẹnẹsisi 6:6nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.

  7. Gẹnẹsisi 6:7nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”

  8. Gẹnẹsisi 6:8nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa.

  9. Gẹnẹsisi 6:9nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìtàn Noa. Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn.

  10. Gẹnẹsisi 6:10nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  11. Gẹnẹsisi 6:11nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú.

  12. Gẹnẹsisi 6:12nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn.

  13. Gẹnẹsisi 6:13nǹkan bí 2448 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú.

  14. Gẹnẹsisi 6:14nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn.

  15. Gẹnẹsisi 6:15nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.

  16. Gẹnẹsisi 6:16nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí.

  17. Gẹnẹsisi 6:17nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun.

  18. Gẹnẹsisi 6:18nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ.

  19. Gẹnẹsisi 6:19nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ.

  20. Gẹnẹsisi 6:20nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè.

  21. Gẹnẹsisi 6:21nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”

  22. Gẹnẹsisi 6:22nǹkan bí 2468 ṣáájú Kristi

    Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.

  23. Gẹnẹsisi 7:1nǹkan bí 2348 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí.

  24. Gẹnẹsisi 7:2nǹkan bí 2348 ṣáájú Kristi

    Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́.

  25. Gẹnẹsisi 7:3nǹkan bí 2348 ṣáájú Kristi

    Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé.