Skip to content

Japheth

11 ẹsẹ · 10 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Japheth

  1. Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  2. Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  3. Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀.

  4. Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.)

  5. Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

  6. Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀, Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

  7. Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

  8. Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.

  9. A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

  10. Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  11. Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.