- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Genealogy
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Kaini sì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni.
Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà.
Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki.
Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla.
Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn.
Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.
Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.
Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.
Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.
Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.
Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.
Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.
Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.
Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.
Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.
Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra.
Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani.
Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti.