Skip to content

Babylon

255 verses · 3 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Babylon's, Sheshach

32.5300, 44.4200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Babylon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima;

  3. Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli ránṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Hesekiah nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Hesekiah.

  4. Nígbà náà Isaiah wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?” “Láti ìlú jíjìn réré,” Hesekiah dáhùn. “Wọ́n wá láti Babeli.”

  5. àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ òní, wọn yí ó gbe lọ sí Babeli, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí.

  6. Àti díẹ̀ nínú àwọn ìran rẹ, ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀, tí wọn yóò bí fún ọ, ni wọn yóò kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babeli.”

  7. Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari.

  8. Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.

  9. Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà,

  10. Nebukadnessari ọba Babeli fúnra rẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í.

  11. Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un. Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n.

  12. Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà.

  13. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.

  14. Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.

  15. Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀. Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.

  16. Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ìjọba Sedekiah. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli yan lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn iṣẹ́ ìdọ̀tí fi yí gbogbo rẹ̀ ká.

  17. wọ́n sì mú un. Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

  18. Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.

  19. Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún kọkàndínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu;

  20. Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà.

  21. Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli.

  22. Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla.

  23. Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

  24. Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda.

  25. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn.