- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Jehoiachin
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.
Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu.
Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà,
Nebukadnessari ọba Babeli fúnra rẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í.
Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un. Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n.
Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa.
Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà.
Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.
Ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn Jehoiakini ọba Juda, ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù, Efili-Merodaki ọba Babeli, ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú.
Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli.
Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
Ní ojoojúmọ́, ọba fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè.
Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn: Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin,
Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Jehoiakini sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa.
“Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.
Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli.
Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.
Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”
Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo, ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́? Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.
Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
Báyìí ni Olúwa wí: “Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere, èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”