Fò sí àkóónú

Jehoiakim

37 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Eliakim

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jehoiakim

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.

  2. Jehoiakimu sì san fún Farao Neko fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.

  3. Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida ọmọbìnrin Pedaiah ó wá láti Ruma.

  4. Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari.

  5. Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda?

  6. Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  7. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe.

  8. Àwọn ọmọ Josiah: àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.

  9. Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, àti Sedekiah.

  10. Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.

  11. Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

  12. Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  13. àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

  14. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’

  15. “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.

  16. Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa.

  17. Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli.

  18. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

  19. Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti.

  20. Ọba Jehoiakimu rán Elnatani ọmọ Akbori lọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.

  21. Wọ́n sì mú Uriah láti Ejibiti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Jehoiakimu; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)

  22. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé.

  23. Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu.

  24. Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ”

  25. Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: