Skip to content

Josiah

49 ẹsẹ · 8 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Josias

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Josiah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”

  2. Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì fi Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ààyè rẹ̀.

  3. Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Ussa. Josiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  4. Josiah jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jedida ọmọbìnrin Adaiah; ó wá láti Boskati.

  5. Ní ọdún kejìdínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé Olúwa. Ó wí pé,

  6. Nígbà náà, Josiah wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn isà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.

  7. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Beteli, Josiah sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Israẹli ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Samaria, tí ó ti mú Olúwa bínú.

  8. Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún tí ọba Josiah, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jerusalẹmu.

  9. Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa.

  10. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Josiah, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?

  11. Nígbà tí Josiah jẹ́ ọba, Farao Neko ọba Ejibiti gòkè lọ sí odò Eufurate láti lọ ran ọba Asiria lọ́wọ́. Ọba Josiah jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Neko dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Megido.

  12. Ìránṣẹ́ Josiah gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Megido sí Jerusalẹmu ó sì sin ín sínú isà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò baba a rẹ̀.

  13. Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.

  14. Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀.

  15. Àwọn ọmọ Josiah: àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.

  16. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì mú Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  17. Josiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

  18. Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.

  19. Síwájú sí i, Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jerusalẹmu, Ọ̀dọ́-àgùntàn àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.

  20. Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba.

  21. Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ.

  22. Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu.

  23. Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah.

  24. Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

  25. Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido.