Skip to content

Shem

17 ẹsẹ · 8 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Sem

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Shem

  1. Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  2. Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  3. Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀.

  4. Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.)

  5. Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

  6. Ó sì tún wí pé, “Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu.

  7. Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀, Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

  8. Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

  9. A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

  10. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

  11. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

  12. Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.

  13. Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  14. Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  15. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu: Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.

  16. Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,

  17. Tí í ṣe ọmọ Kainani, tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu, tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,