Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Arphaxad
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.
Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.
Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.
Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu: Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.
Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.