Skip to content

Persia

25 verses

34.7900, 48.5100 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Persia

  1. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára.

  2. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

  3. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

  4. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,

  5. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.

  6. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

  7. Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ.

  8. Ṣùgbọ́n Serubbabeli, Jeṣua àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Israẹli dáhùn pé, “Ẹ kò ní ohunkóhun pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, bí Kirusi, ọba Persia, ti pàṣẹ fún wa.”

  9. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Kirusi ọba Persia àti títí dé ìgbà ìjọba Dariusi ọba Persia.

  10. Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́.

  11. Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dariusi ọba Persia.

  12. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀.

  13. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah,

  14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Persia: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntun láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ ṣe, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Juda àti ní Jerusalẹmu.

  15. ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  16. àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.

  17. Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.

  18. Gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia?

  19. “ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.

  20. Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn

  21. Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Media àti Persia.

  22. Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.

  23. Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́ mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia.

  24. Nígbà náà, ni ó wí pé, “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ-aládé Persia jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ-aládé Giriki yóò wá;

  25. “Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki.