Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Medo-Persian Kingdom

62 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

  2. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára.

  3. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

  4. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

  5. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,

  6. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.

  7. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu.

  8. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

  9. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahaswerusi wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu.

  10. Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́.

  11. Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli.

  12. A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí.

  13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀.

  14. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.

  15. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah,

  16. Artasasta, ọba àwọn ọba. Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run. Àlàáfíà.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.

  18. Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje (127) ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia.

  19. Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa,

  20. ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  21. Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.

  22. Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa.

  23. Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí.

  24. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.

  25. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,