Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Medo-Persian Kingdom: Deliverance of the Jews

5 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Deliverance of the Jews

  1. ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”

  2. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.

  3. Èmi yóò lọ síwájú rẹ, Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.

  4. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

  5. Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.