Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Cyrus

27 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

  2. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

  3. Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,

  4. “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda.

  5. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu.

  6. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

  7. Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu.

  8. Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.

  9. Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀.

  10. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

  11. Èyí ni iye wọn. Ọgbọ̀n àwo wúrà 30 Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000 Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n 29

  12. Ọgbọ̀n àdému wúrà 30 Irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410 Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000

  13. Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé irinwó (5,400). Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.

  14. “Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.

  15. Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní Babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀,

  16. Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.

  17. Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.

  18. Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.

  19. A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́, olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.

  20. Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.

  21. Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

  22. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.

  23. Èmi yóò lọ síwájú rẹ, Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.

  24. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

  25. Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.