Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Cyrus: Prophecies concerning

12 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophecies concerning

  1. Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.

  2. Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.

  3. Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.

  4. A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́, olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.

  5. Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.

  6. Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

  7. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.

  8. Èmi yóò lọ síwájú rẹ, Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.

  9. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

  10. Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.

  11. “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́. Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí. Olúwa ti fẹ́ ẹ, yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni, apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.

  12. Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.