- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Genealogy
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea.
Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska.
Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.
Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.
Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani.
Èyí ni ìran Peresi: Peresi ni baba Hesroni,
Hesroni ni baba Ramu, Ramu ni baba Amminadabu
Amminadabu ni baba Nahiṣoni, Nahiṣoni ni baba Salmoni,
Salmoni ni baba Boasi, Boasi ni baba Obedi,
Obedi ní baba Jese, Jese ni baba Dafidi.
Adamu, Seti, Enoṣi,
Kenani, Mahalaleli, Jaredi,
Enoku, Metusela, Lameki, Noa.
Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti, àti Kenaani.
Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama: Ṣeba àti Dedani.
Kuṣi sì bí Nimrodu ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu,
Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti,
àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,