Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Genealogy

114 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. nínú àwọn ọmọ Joabu: Obadiah ọmọ Jehieli àti ogún ó lé nígba ó dín méjì (218) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

  2. nínú àwọn ọmọ Bani: Ṣelomiti ọmọ Josafiah, àti ọgọ́jọ ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

  3. nínú àwọn ọmọ Bebai: Sekariah ọmọ Bebai àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;

  4. nínú àwọn ọmọ Asgadi: Johanani ọmọ Hakatani, àti àádọ́fà ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

  5. nínú àwọn ọmọ Adonikami: àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orúkọ wọn ń jẹ́ Elifaleti, Jeieli àti Ṣemaiah, àti ọgọ́ta ọkùnrin pẹ̀lú wọn;

  6. nínú àwọn ọmọ Bigfai: Uttai àti Sakkuri, àti àádọ́rin ọkùnrin pẹ̀lú wọn.

  7. Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń sàn lọ sí Ahafa, a pàgọ́ síbẹ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárín àwọn ènìyàn àti àárín àwọn àlùfáà, ń kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.

  8. Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

  9. Abrahamu ni baba Isaaki; Isaaki ni baba Jakọbu; Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

  10. Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu;

  11. Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni;

  12. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  13. Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

  14. Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa,

  15. Asa ni baba Jehoṣafati; Jehoṣafati ni baba Jehoramu; Jehoramu ni baba Ussiah;

  16. Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah;

  17. Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah;

  18. Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

  19. Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli: Jekoniah ni baba Ṣealitieli; Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

  20. Serubbabeli ni baba Abihudi; Abihudi ni baba Eliakimu; Eliakimu ni baba Asori;

  21. Asori ni baba Sadoku; Sadoku ni baba Akimu; Akimu ni baba Elihudi;

  22. Elihudi ni baba Eleasari; Eleasari ni baba Mattani; Mattani ni baba Jakọbu;

  23. Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

  24. Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Eli,

  25. tí í ṣe ọmọ Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,