Magog
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Magog
Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i
Èmi yóò fi iná sí Magogu àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun.