Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Millennium

41 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

  2. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.

  3. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.

  4. “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán; ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé; ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú.

  5. Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.

  6. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́.

  7. Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán, wọn kí yóò bímọ fún wàhálà; nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.

  8. Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn; nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.

  9. Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.

  10. Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.

  11. Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.

  12. Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké. Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”

  13. Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

  14. Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.

  15. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà.

  16. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.

  17. Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà.

  18. Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.

  19. Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.

  20. Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  21. Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.

  22. Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”

  23. Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”

  24. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

  25. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’ nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà.