Skip to content

Satan

55 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Beelzebub

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Satan

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli.

  2. Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn.

  3. Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

  4. Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”

  5. Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?”

  6. Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.

  7. Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa.

  8. Olúwa sì bi Satani pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Satani sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

  9. Olúwa sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.”

  10. Satani sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.

  11. Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”

  12. Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.

  13. Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

  14. Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.

  15. Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”

  16. Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

  17. Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

  18. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

  19. Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró?

  20. Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín.

  21. Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.”

  22. Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

  23. Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

  24. Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde?

  25. Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.