Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Persecution

270 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

  2. Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti.

  3. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa.

  4. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”

  5. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao.

  6. Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tànkálẹ̀. Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli.

  7. Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa.

  8. Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò.

  9. Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi.

  10. Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”

  11. kí ẹ sì wí pé, ‘Báyìí ni ọba wí: Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà.’ ”

  12. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  13. Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

  14. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

  15. Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

  16. Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀ yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

  17. Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini. Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,

  18. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.

  19. Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera, ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.

  20. Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,” àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

  21. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?

  22. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.

  23. Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.

  24. Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

  25. “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”